Lagos TelevisionLagos Television (tí a pè ni LTV ), tàbí Lagos Weekend Television (tí a pè ni LWT, ìkànnì UHF 35, tí a tún mọ̀ sí LTV 8 ).[1] Ó jẹ́ ilé-iṣẹ́ tẹlifisiọnu tí ìjọba ní Ikeja, Lagos, Nigeria . Wọ́n dá Lagos state television sílẹ̀ ní oṣù kẹwàá, ọdún 1980 lábẹ́ ìṣàkóso Alhaji Lateef Jakande láti pín ìsọfúnni kálẹ̀ àti láti ṣe àwọn aráàlú láre. Ó di ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán kejì ti ìjọba ìpínlẹ̀ kan dá sílẹ̀, tí Broadcasting Corporation ti Ìpínlẹ̀ Òyó (BCOS) tẹ̀le.[2] Ó bẹ̀rẹ̀ ìkéde ní Oṣù kọkànlá ọjọ́ kẹsan ti ọdún yẹn àti pé ó jẹ́ ilé-iṣẹ́ Telifisonu àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn igbòhùnsáfẹ́fẹ́ / àwọn ẹgbẹ́ VHF àti UHF meji. Ní báyìí, lórí ìkànnì UHF 35, ó jẹ́ ilé-iṣẹ́ Telifisonu ti ìpínlẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó ní lórí okùn satẹlaiti DSTV ìkànnì 256 ó sì padà wa lori ìkànnì Startimes 104.[3] Èrò Lagos Television ni láti gba ìjọba ìpínlẹ̀ láàyè láti tan káàkiri alaye àti kí ó gba gbogbo aráàlú lára yá àti isópọ̀ láàrin ìjọba àti aráàlú.[4] Lábẹ́ ìjọba ológun, wọ́n sún Lagos Television si ìkànnì UHF 35.[5] Ní Oṣù Kẹsan ọdún 1985, iná aramada kan run gbogbo ibùdó náà, ilé-iṣere rẹ̀, ilé-ìkàwé àti àwọn igbasilẹ òṣìṣẹ́ náà si bàjẹ́.[6] Àwọn ìtọ́kasí
Information related to Lagos Television |